Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:5 - Yoruba Bible

5 ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:5
30 Iomraidhean Croise  

Ẹ jẹ́ kí wọ́n bu omi wá kí ẹ fi ṣan ẹsẹ̀, kí ẹ sì sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi níhìn-ín.


Ó ní, “Ẹ̀yin oluwa mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yà sí ilé èmi iranṣẹ yín, kí ẹ ṣan ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sùn ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ìdájí ọ̀la, kí ẹ máa bá tiyín lọ.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Ó tì o! ìta gbangba láàrin ìlú ni a fẹ́ sùn.”


Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ.


Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”


Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!


“Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.


Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.


N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.


Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.


OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.


ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.


Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún.


Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”


Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?”


Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”


Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde.


Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.


Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.


Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.


tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.


Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.


Òun yìí ni ó wà nípa omi ati ẹ̀jẹ̀, àní Jesu Kristi. Kì í ṣe nípa omi nìkan, ṣugbọn nípa omi ati ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀mí ni ó ń jẹ́rìí, nítorí òtítọ́ ni Ẹ̀mí.


ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.


Baba náà bá mú wọn lọ sí ilé rẹ̀, ó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní koríko. Wọ́n ṣan ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.


Abigaili bá wólẹ̀ ó ní, “Iranṣẹ Dafidi ni mí, mo sì ti ṣetán láti ṣan ẹsẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan