Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:4 - Yoruba Bible

4 Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:4
9 Iomraidhean Croise  

Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?” Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”


Àwọn ẹrú tí oluwa wọn bá dé, tí ó bá wọn, tí wọn ń ṣọ́nà, ṣe oríire. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo di ara rẹ̀ ní àmùrè, yóo fi wọ́n jókòó lórí tabili, yóo wá gbé oúnjẹ ka iwájú wọn.


“Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun?


Àbí yóo sọ fún iranṣẹ náà pé, ‘Tọ́jú ohun tí n óo jẹ. Ṣe gírí kí o gbé oúnjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹ tìrẹ.’


Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ.


Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín?


Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.


Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan