Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:23 - Yoruba Bible

23 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:23
15 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni.


Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba.


“Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín.


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”


Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”


Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru.


Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.


Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”


Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”


Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”


Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”


Ọmọ-ẹ̀yìn náà ni ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi. Òun ni ó kọ nǹkan wọnyi: a mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.


Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan