Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:2 - Yoruba Bible

2 Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:2
14 Iomraidhean Croise  

Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu,


Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn.


Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.


Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.


“Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà.


Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.”


Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí,


Peteru bá bi í pé, “Anania, kí ló dé tí Satani fi gbà ọ́ lọ́kàn tí o fi ṣe èké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí o fi yọ sílẹ̀ ninu owó tí o rí lórí ilẹ̀ náà?


Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu.


Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù.


Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan