Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:3 - Yoruba Bible

3 Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nigbana ni Maria mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabùla, olowo iyebiye, o si nfi kùn Jesu li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù: ile si kún fun õrùn ikunra na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:3
16 Iomraidhean Croise  

Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA, tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,


ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró, tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.


Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.


Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.


Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi, ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ. Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.


Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”


O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀.


Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.


Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.”


Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”


Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan