Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:13 - Yoruba Bible

13 Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:13
19 Iomraidhean Croise  

Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní, “Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin; lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.


Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israẹli yóo pada tọ OLUWA Ọlọrun wọn, ati Dafidi, ọba wọn lọ. Wọn yóo fi ìbẹ̀rù wá sọ́dọ̀ OLUWA, wọn yóo sì gba oore rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.


Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje.


OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò, ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ. OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín; ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́.


Nítorí náà, mo sọ fun yín pé ẹ kò ní fojú kàn mí mọ́ títí di àkókò tí ẹ óo wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa!’ ”


“Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́.


Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.”


Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,


“Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni, Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”


Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?” Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.”


wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé, “Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare. Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ, Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.


A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”


Lẹ́yìn náà, mo rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ẹnikẹ́ni kò lè kà láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà, ati oríṣìíríṣìí èdè, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan. Wọ́n wọ aṣọ funfun. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ lọ́wọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan