Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:54 - Yoruba Bible

54 Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

54 Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

54 Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:54
9 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ.


Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀.


Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ.


Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu.


nítorí kò sí ẹni tíí fi ohun tí ó bá ń ṣe pamọ́, bí ó bá fẹ́ kí àwọn eniyan mọ òun. Tí o bá ń ṣe nǹkan wọnyi, fi ara rẹ han aráyé.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan