Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:53 - Yoruba Bible

53 Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

53 Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:53
22 Iomraidhean Croise  

Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á.


Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.


Láti ọjọ́ náà, ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ mi ní ń bá iṣẹ́ odi mímọ lọ, ìdajì yòókù sì dira pẹlu ọ̀kọ̀, àṣíborí, ọrun ati aṣọ ogun. Àwọn ìjòyè sì wà lẹ́yìn gbogbo àwọn eniyan Juda,


Kí á yin orúkọ OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.


Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.


Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.


Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi, àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,


Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.”


Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.”


Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.


Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde.


Kò sí ẹnìkan tí ó lè dá a lóhùn ọ̀rọ̀ yìí. Láti ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni kò ní ìgboyà láti tún bi í ní ohunkohun mọ́.


Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á.


Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á.


Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á.


Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á.


Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ?


Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Ọ̀rọ̀ yìí gún àwọn tí ó gbọ́ ọ lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ pa wọ́n.


Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan