Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:51 - Yoruba Bible

51 Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

51 Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:51
23 Iomraidhean Croise  

Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA.


Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé.


Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?”


ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,


Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”


gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.


Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan!


wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà.


Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan.


Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀.


Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.”


Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.


Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.


Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu.


Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun.


Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan