Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:32 - Yoruba Bible

32 Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

32 Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:32
10 Iomraidhean Croise  

Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni.


Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”


Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé,


Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.


Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú!


Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”


Ìjòyè náà bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, tètè wá kí ọmọ mi tó kú.”


Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí.


Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.


Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan