Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:21 - Yoruba Bible

21 Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nigbana ni Marta wi fun Jesu pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kì ba tí kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:21
12 Iomraidhean Croise  

Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.”


Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní, “Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?


Wọ́n dán an wò léraléra, wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú.


Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”


Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.


Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”


Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”


Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan