Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:1 - Yoruba Bible

1 Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:1
15 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò.


Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn.


Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;


Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.”


Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ.


Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn.


Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”


Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí.


Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú.


Ní àkókò yìí ó wá ṣàìsàn, ó sì kú. Wọ́n bá wẹ̀ ẹ́, wọ́n tẹ́ ẹ sí yàrá lókè ní ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan