Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:9 - Yoruba Bible

9 Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:9
16 Iomraidhean Croise  

Nítorí òun ni Ọlọrun wa, àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri, àwa ni agbo aguntan rẹ̀. Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,


Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.


Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”


N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA, wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.”


“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni.


Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ.


Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan