Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:7 - Yoruba Bible

7 Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:7
12 Iomraidhean Croise  

Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.


Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.


Nítorí òun ni Ọlọrun wa, àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri, àwa ni agbo aguntan rẹ̀. Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,


Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀, OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.


“Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.


Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”


“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni.


Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ.


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan