Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:29 - Yoruba Bible

29 Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

29 Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:29
12 Iomraidhean Croise  

OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ; àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.


Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.”


“Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an! Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ! Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀, àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba.


Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.


Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́.


Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.”


Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ.


Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan.


Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un.


“Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.


“Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n.


Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan