Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:2 - Yoruba Bible

2 Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:2
25 Iomraidhean Croise  

OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi, n kò ní ṣe àìní ohunkohun.


Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́


Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ ni àkójọ òwe tí olùṣọ́-aguntan kan bá sọ dàbí ìṣó tí a kàn tí ó dúró gbọningbọnin.


Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.


Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́, ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀. Wọ́n bèèrè pé, ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà? Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀, tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?


Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.


Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia. Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà.


Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran, nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́. Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù, nítorí igbó tí wọn ń gbé lẹ́bàá odò Jọdani ti parun!


Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.”


Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké.


Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”


Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí,


Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.


Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ.


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí.


Ìdí tí mo ṣe fi ọ́ sílẹ̀ ní Kirete ni pé kí o ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó kù tí kò dára tó, kí o sì yan àwọn àgbà lórí ìjọ ní gbogbo ìlú, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlànà fún ọ.


Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin.


Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín.


Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá.


Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan