Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:15 - Yoruba Bible

15 gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:15
25 Iomraidhean Croise  

Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.


Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́, ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè, ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?


Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.


Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”


Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.


Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.


Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.


Kò sí ẹni tí ó rí Baba rí àfi ẹni tí ó ti wà pẹlu Baba ni ó ti rí Baba.


Ẹ kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́n. Bí mo bá sọ pé èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóo di òpùrọ́ bíi yín. Ṣugbọn mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.


ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ ayé wa burúkú yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun Baba wa,


Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.”


Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.


ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.


Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.


Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.


Òun fúnrarẹ̀ ni ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Kì í ṣe tiwa nìkan, ṣugbọn ti gbogbo ayé pẹlu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan