Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:14 - Yoruba Bible

14 Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:14
23 Iomraidhean Croise  

Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.


Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.


Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.


OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò.


“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.


nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan.


Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi.


Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.


Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.


Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.


Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára.


kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.


Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu.


Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà.


Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.”


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.


Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n.


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Sadi: “Ẹni tí ó ní Ẹ̀mí Ọlọrun meje ati ìràwọ̀ meje ní: Mo mọ iṣẹ́ rẹ. O kàn ní orúkọ pé o wà láàyè ni, òkú ni ọ́!


Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ̀ pé o kò gbóná, bẹ́ẹ̀ ni o kò tutù. Ninu kí o gbóná tabi kí o tutù, ó yẹ kí o ṣe ọ̀kan.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan