Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:5 - Yoruba Bible

5 Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:5
10 Iomraidhean Croise  

“Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín? Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn, tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?


Wọn kì í tan fìtílà tán kí wọ́n fi igbá bò ó; lórí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà. Yóo wá fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ó wà ninu ilé.


Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n.


Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’


Nígbà tí wọn kò ka ìmọ̀ Ọlọrun sí, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ọkàn wọn tí kò tọ́, kí wọn máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ.


Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan