Johanu 1:49 - Yoruba Bible49 Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.” Faic an caibideilBibeli Mimọ49 Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní49 Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.” Faic an caibideil |
Mọ èyí, kí ó sì yé ọ, pé láti ìgbà tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerusalẹmu kọ́, di ìgbà tí ẹni àmì òróró Ọlọrun, tíí ṣe ọmọ Aládé, yóo dé, yóo jẹ́ ọdún meje lọ́nà meje. Lẹ́yìn náà, ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje ni a óo sì fi tún un kọ́, yóo ní òpópónà, omi yóo sì yí i po; ṣugbọn yóo jẹ́ àkókò ìyọnu.