Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:46 - Yoruba Bible

46 Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

46 Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

46 Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?” Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:46
14 Iomraidhean Croise  

Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu.


Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”


“Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà?


Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi.


Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”


Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”


Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.”


“Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”


Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”


Filipi dá a lóhùn pé, “Burẹdi igba owó fadaka kò tó kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi rí díẹ̀díẹ̀ panu!”


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!”


Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan