Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:45 - Yoruba Bible

45 Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

45 Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

45 Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:45
41 Iomraidhean Croise  

Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”


N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”


Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.


Tí ó bá di ìgbà náà, ẹ̀ka igi OLUWA yóo di ohun ẹwà ati iyì. Èso ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ògo ati àmúyangàn fún àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá kù.


Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ. Ìrísí rẹ̀ kò dára, ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan.


Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.


Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


Kí o sì sọ ohun tí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí fún un, pé, ‘Wò ó! Ọkunrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka ni yóo gba ipò rẹ̀, òun ni yóo sì kọ́ ilé OLUWA.


Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.


Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu.


Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi?


Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”


Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”


Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”


Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́.


Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”


Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.


Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ bá bi í pé, “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Èmi ati baba rẹ dààmú pupọ nígbà tí à ń wá ọ.”


Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.


Ó bá sọ fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ tí mo sọ fun yín nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìyí, pé dandan ni kí ohun gbogbo tí a sọ nípa mi kí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ wọ́n sílẹ̀ ninu ìwé Òfin Mose ati ninu ìwé àwọn wolii ati ninu ìwé Orin Dafidi.”


Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli,


Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”


Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi.


Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”


Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.”


Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.” Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.


Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”


Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.”


Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan.


Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?”


Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”


Filipi dá a lóhùn pé, “Burẹdi igba owó fadaka kò tó kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi rí díẹ̀díẹ̀ panu!”


Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


“Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.


Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’


“Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán?


Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan