Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:42 - Yoruba Bible

42 Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

42 O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:42
20 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba.


Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.


Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru,


Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”


Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu,


“Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’


Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan.


Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.”


Ohun tí mò ń wí ni pé olukuluku yín ní ń sọ tirẹ̀. Bí ẹnìkan ti ń wí pé. “Ẹ̀yìn Paulu ni èmi wà,” ni ẹlòmíràn ń wí pé. “Ẹ̀yìn Apolo ni èmi wà,” tí ẹlòmíràn tún ń wí pé, “Ẹ̀yìn Peteru ni mo wà ní tèmi.” Ẹlòmíràn sì ń wí pé, “Ẹ̀yìn Kristi ni èmi wà.”


Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.


ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo.


Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru?


Lẹ́yìn ọdún mẹta ni mo tó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rí Peteru, mo sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹẹdogun.


Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí.


Nígbà tí Jakọbu, Peteru ati Johanu, tí àwọn eniyan ń wò bí òpó ninu ìjọ, rí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun ti fi fún mi, wọ́n bọ èmi ati Banaba lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdàpọ̀, wọ́n ní kí àwa lọ sáàrin àwọn tí kì í ṣe Juu bí àwọn náà ti ń lọ sáàrin àwọn tí ó kọlà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan