Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:17 - Yoruba Bible

17 Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:17
37 Iomraidhean Croise  

Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”


N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”


Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé; òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.


Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli; gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.


O óo fi òtítọ́ inú hàn sí Jakọbu, o óo sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba wa láti ìgbà àtijọ́.


Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”


Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn.


Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?”


ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.”


Àwa mọ̀ pé Ọlọrun ti bá Mose sọ̀rọ̀, ṣugbọn a kò mọ ibi tí eléyìí ti yọ wá.”


Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.


Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa.


Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà.


Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun.


Kókó ohun tí mò ń sọ ni pé òfin tí ó dé lẹ́yìn ọgbọnlenirinwo (430) ọdún kò lè pa majẹmu tí Ọlọrun ti ṣe rẹ́. Ìlérí tí Ọlọrun ti ṣe kò lè torí rẹ̀ di òfo.


nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin, tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.


Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní àwọn òfin;


Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn.


Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan