Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:16 - Yoruba Bible

16 Nítorí láti inú ẹ̀kún ibukun rẹ̀ ni gbogbo wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà kún oore-ọ̀fẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:16
24 Iomraidhean Croise  

Wọn ó máa ní agbára kún agbára, títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.


Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ”


Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.


Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́.


Ṣugbọn Johanu fẹ́ kọ̀ fún un, ó ní, “Èmi gan-an ni mo nílò pé kí o ṣe ìrìbọmi fún mi; ìwọ ni ó tún tọ̀ mí wá?”


nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.


Nítorí pé ẹni tí Ọlọrun rán wá ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí pé Ọlọrun fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀.


Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi.


Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí.


Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni òfin gbà wọlé, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè pọ̀ jantirẹrẹ. Níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá sì ti pọ̀, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun a máa pọ̀ ju bí ẹ̀ṣẹ̀ ti pọ̀ tó lọ.


Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi.


Ìjọ ni ara Kristi, Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun gbogbo. Òun ni ó ń mú ohun gbogbo kún.


kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.


Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí.


Wọ́n ń wádìí nípa ẹni náà ati àkókò náà, tí Ẹ̀mí Kristi tí ó wà ninu wọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà tí Kristi níláti jẹ, ati bí yóo ti ṣe bọ́ sinu ògo lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀.


Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan