Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:15 - Yoruba Bible

15 Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:15
21 Iomraidhean Croise  

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.


Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.


OLUWA ní, “Ṣugbọn, ìwọ Bẹtilẹhẹmu ní Efurata, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kéré láàrin gbogbo ẹ̀yà Juda, sibẹ láti inú rẹ ni ẹni tí yóo jẹ́ aláṣẹ Israẹli yóo ti jáde wá fún mi, ẹni tí ìran tí ó ti ṣẹ̀ jẹ́ ti ayérayé, tí ó ti wà láti ìgbà laelae.”


Ìrìbọmi ni èmi fi ń wẹ̀ yín mọ́ nítorí ìrònúpìwàdà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn mi jù mí lọ; èmi kò tó ẹni tí ó lè kó bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni òun yóo fi wẹ̀ yín mọ́.


Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀.


Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́.


ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”


Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi.


Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.”


Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò.


Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae.


ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana: “Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan