Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joẹli 3:3 - Yoruba Bible

3 Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joẹli 3:3
8 Iomraidhean Croise  

Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn, ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.


Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà.


Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini, nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín.


OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji.


Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ, tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn, tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu, ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n; ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn.


Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.


oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan