Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 7:3 - Yoruba Bible

3 Ó ní, “Ẹ má ì tíì ṣe ilẹ̀ ayé ati òkun ati àwọn igi ní jamba títí tí a óo fi fi èdìdì sí àwọn iranṣẹ Ọlọrun wa níwájú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 7:3
31 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà.


Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín.


OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀, ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn; ó lé wọn jáde ní ìlú, bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn.


Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà tí yóo lágbára lórí rẹ. Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́, ni o óo jàre wọn. Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA, ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá àwọn eniyan náà ni ó kù ní ilẹ̀ náà, sibẹsibẹ iná yóo tún jó o bí igi terebinti tabi igi Oaku, tí kùkùté rẹ̀ wà lórí ilẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gé e lulẹ̀.” Èso mímọ́ ni kùkùté rẹ̀.


“Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà, tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́, nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi, n kò ní pa gbogbo wọn run.


OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”


Ẹ pa àwọn àgbàlagbà patapata, ati àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin pẹlu, ati àwọn ọmọde ati àwọn obinrin. Ṣugbọn ẹ má fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni tí àmì bá wà níwájú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́ mi.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà níwájú ilé OLUWA.


Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.


Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ.


Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.”


Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.


Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ óo tún rí ìyàtọ̀ láàrin àwọn eniyan rere tí wọn ń sin Ọlọrun, ati àwọn ẹni ibi tí wọn kì í sìn ín.”


Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù.


Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji.


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.”


Ẹni tí ó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ gbà dájúdájú pé olóòótọ́ ni Ọlọrun.


Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí.


Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn.


Kò sí ẹni tí ó lè ra ohunkohun tabi kí ó ta ohunkohun àfi ẹni tí ó bá ní àmì orúkọ ẹranko náà tabi ti iye orúkọ rẹ̀ lára.


Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.


Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀,


Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.”


Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.


Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn.


Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.”


Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi.


Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba.


A sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe ohunkohun sí koríko orí ilẹ̀ tabi sí ewébẹ̀ tabi sí igi kan. Gbogbo àwọn eniyan tí kò bá ní èdìdì Ọlọrun ní iwájú wọn nìkan ni kí wọ́n ṣe léṣe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan