Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 4:3 - Yoruba Bible

3 Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 4:3
13 Iomraidhean Croise  

wọ́n sì rí Ọlọrun Israẹli. Wọ́n rí kinní kan ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó dàbí pèpéle tí a fi òkúta safire ṣe, ó mọ́lẹ̀ kedere bí ojú ọ̀run.


Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi.


wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji,


Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.


Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà.


Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀.


Lẹ́yìn náà, mo wo orí àwọn Kerubu, mo rí kinní kan róbótó róbótó, wọ́n dàbí òkúta safire, ìrísí wọn dàbí ìtẹ́.


O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.


Mo tún rí angẹli alágbára mìíràn, tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó fi ìkùukùu bora, òṣùmàrè sì yí orí rẹ̀ ká; ojú rẹ̀ dàbí oòrùn; ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó iná.


Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan