Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 3:3 - Yoruba Bible

3 Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nitorina ranti bi iwọ ti gbà, ati bi iwọ ti gbọ́, ki o si pa a mọ, ki o si ronupiwada. Njẹ, bi iwọ kò ba ṣọra, emi o de si ọ bi olè, iwọ kì yio si mọ̀ wakati ti emi o de si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 3:3
24 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe.


Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín.


“Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tabi àkókò.


Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nà nítorí ẹ kò mọ wakati náà.


Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun.


Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí.


Timoti mi ọ̀wọ́n, pa ìṣúra tí a fi fún ọ mọ́. Di etí rẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ játijàti tí kò ṣeni ní anfaani ati àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń ṣì pè ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n. Àṣìpè ni, nítorí pé wọ́n kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lòdì sí ara wọn.


Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu.


Nítorí náà, ó yẹ kí á túbọ̀ ṣe akiyesi àwọn ohun tí à ń gbọ́, kí á má baà gbá wa lọ bí ìgbà tí odò gbá nǹkan lọ.


Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí.


Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀.


Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.


“Bí olè ni mò ń bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣọ́nà ṣe oríire, tí olúwarẹ̀ wọ aṣọ rẹ̀, kí ó má baà sí ní ìhòòhò, kí ojú má baà tì í níwájú àwọn eniyan.”


Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé.


Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀.


“Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.”


Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.


Àwọn tí mo bá fẹ́ràn ni mò ń bá wí, àwọn ni mò ń tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ní ìtara, kí o sì ronupiwada.


Jí lójú oorun! Fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́kù ní okun, nítorí àwọn náà ń kú lọ. Nítorí n kò rí iṣẹ́ kan tí o ṣe parí níwájú Ọlọrun mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan