Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 2:3 - Yoruba Bible

3 O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 2:3
49 Iomraidhean Croise  

Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é.


Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn, tí ìtìjú sì bò mí.


N óo fara da ìyà tí OLUWA bá fi jẹ mí Nítorí pé mo ti ṣẹ̀ ẹ́, títí tí yóo fi gbèjà mi, tí yóo sì dá mi láre. Yóo mú mi wá sinu ìmọ́lẹ̀; ojú mi yóo sì rí ìdáǹdè rẹ̀.


Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu.


Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.


Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀.


Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín.


Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.”


Àwọn ti ilẹ̀ dáradára ni àwọn tí ó fi ọkàn rere ati ọkàn mímọ́ gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso nípa ìfaradà.


Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura.


Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa.


yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́.


Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.


Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo.


Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.


A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa.


Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà.


Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ.


Nítorí èyí, kì báà jẹ́ pé a wà ninu ilé ti ibí, tabi kí á bọ́ sinu ilé ti ọ̀hún, àníyàn wa ni pé kí á sá jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Oluwa.


nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú.


Ẹ máa ran ara yín lẹ́rù, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú òfin Kristi ṣẹ.


Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá.


tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.


Bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ ìwọ náà, ẹlẹgbẹ́ mi tòótọ́, ran àwọn obinrin wọnyi lọ́wọ́, nítorí wọ́n ti bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìtànkálẹ̀ ìyìn rere pẹlu Kilẹmẹnti ati gbogbo olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù, àwọn tí orúkọ wọn wà ninu ìwé ìyè.


Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀.


Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà.


Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.


Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú.


Ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí rere su yín í ṣe.


Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín.


Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára.


Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.


Ó yẹ kí àwọn àgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ aṣiwaju dáradára gba ìdálọ́lá ọ̀nà meji, pataki jùlọ àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ oníwàásù ati olùkọ́ni.


Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe.


Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà.


Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.


kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun.


Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù.


Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà.


Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi.


Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan