Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 19:4 - Yoruba Bible

4 Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Awọn àgba mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹda alãye mẹrin nì si wolẹ, nwọn si foribalẹ fun Ọlọrun ti o joko lori itẹ́, wipe, Amin; Halleluiah.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé: “Àmín, Haleluya!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 19:4
20 Iomraidhean Croise  

Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae!” Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.


Mo gbọn àpò ìgbànú mi, mo ní, “Báyìí ni Ọlọrun yóo gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ kúrò ninu ilé rẹ̀ ati kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Ọlọrun yóo gbọn olúwarẹ̀ dànù lọ́wọ́ òfo.” Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà sì ṣe “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA. Àwọn eniyan náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ.


Ẹsira yin OLUWA, Ọlọrun, tí ó tóbi, gbogbo àwọn eniyan náà gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n dáhùn pé “Amin, Amin,” wọ́n tẹríba, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.


Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi! Yin OLUWA!


Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!” Ẹ yin OLUWA!


Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Amin! Amin!


Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí, kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan! Amin! Amin.


Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae! Amin! Amin!


ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí.


Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”


Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’


Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ?


Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.


Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa.


Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.”


Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.


Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan