Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 19:2 - Yoruba Bible

2 Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbere nla nì, ti o fi àgbere rẹ̀ ba ilẹ aiye jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 19:2
16 Iomraidhean Croise  

O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.


Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.


OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi. N óo gbé ọ ga: n óo yin orúkọ rẹ. Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu, o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́, o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.


Ṣugbọn ìdájọ́ yóo bẹ̀rẹ̀, a óo gba àṣẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, a óo sì pa á run patapata.


Èmi OLUWA ni ẹlẹ́san, n óo sì gbẹ̀san, nítorí ọjọ́ ń bọ̀, tí àwọn pàápàá yóo yọ̀ ṣubú. Ọjọ́ ìdààmú wọn kù sí dẹ̀dẹ̀, ọjọ́ ìparun wọn sì ń bọ̀ kíákíá.


“Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.


“Ẹ máa yìn ín ẹ̀yin eniyan OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, nítorí pé yóo gbẹ̀san lára àwọn tí wọ́n bá pa àwọn iranṣẹ rẹ̀. Yóo sì jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ níyà, yóo sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀.”


wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé, “Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare. Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ, Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.


Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!”


Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”


Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan