Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 19:1 - Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LẸHIN nkan wọnyi mo gbọ́ ohùn nla li ọrun bi ẹnipe ti ọ̀pọlọpọ enia, nwipe Halleluiah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé: “Haleluya! Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 19:1
23 Iomraidhean Croise  

Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”


OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.


Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’


Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.


Mo wá gbọ́ ohùn líle kan ní ọ̀run tí ó sọ pé, “Àkókò ìgbàlà nìyí ati ti agbára, ati ìjọba ti Ọlọrun wa, ati àkókò àṣẹ Kristi rẹ̀. Nítorí a ti lé Olùfisùn àwọn onigbagbọ ara wa jáde, tí ó ń fi ẹjọ́ wọn sùn níwájú Ọlọrun wa tọ̀sán-tòru.


Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ yìn ín lókè ọ̀run.


Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!”


Ẹ yin OLUWA! Ẹ yin Ọlọrun ninu ibi mímọ́ rẹ̀; ẹ yìn ín ninu òfuurufú rẹ̀ tí ó lágbára.


Ẹ yin OLUWA! Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.


Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae. Ẹ máa yin OLUWA.


Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.


OLUWA níí gbani, kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.


Ẹ yin OLUWA! Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.


Ẹ yin OLUWA! N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn, láàrin àwọn olódodo, ati ní àwùjọ àwọn eniyan.


Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan, mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé, Ọlọrun ló ni agbára;


Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi! Yin OLUWA!


Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn, yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni, nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan