Ìfihàn 17:4 - Yoruba Bible4 Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ4 A si fi aṣọ elese aluko ati aṣọ odòdó wọ obinrin na, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perli ṣe e lọṣọ́, o ni ago wura kan li ọwọ́ rẹ̀, ti o kún fun irira ati fun ẹgbin àgbere rẹ̀: Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; Faic an caibideil |
OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn.
“Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ, ati ẹni tí ó pa eniyan; kò sí ìyàtọ̀. Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa. Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ, ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ, bákan náà ni wọ́n rí. Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí, kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa. Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.