Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 10:3 - Yoruba Bible

3 Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 10:3
16 Iomraidhean Croise  

À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.


Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.


Nítorí OLUWA sọ fún mi pé, “Bí kinniun tabi ọmọ kinniun ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa, tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan, tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀, tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á; bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀, yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.


OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin, ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun, ó kígbe, ó sì bú ramúramù. Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA ní:


Bíbú wọn dàbí ti kinniun, wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun, wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀, wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn.


“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé: ‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè, yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀. Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀. Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.


Ariwo ìyẹ́ àwọn Kerubu náà dé àgbàlá òde. Ó dàbí ìgbà tí Ọlọrun Olodumare bá ń sọ̀rọ̀.


“Àwọn ọmọ Israẹli yóo wá mi, n óo sì bú bíi kinniun; lóòótọ́ n óo bú, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin yóo sì fi ìbẹ̀rùbojo jáde wá láti ìwọ̀ oòrùn;


OLUWA kígbe láti Sioni, ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu; ọ̀run ati ayé mì tìtì, ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀, òun ni ibi ààbò fún Israẹli.


Amosi ní: “OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni, ó fọhùn ní Jerusalẹmu; àwọn pápá tútù rọ, ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.”


“Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà? “OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?”


Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn.


Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin.


Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.


Mànàmáná ati ìró ààrá ń jáde láti ara ìtẹ́ tí ó wà láàrin. Ògùṣọ̀ meje tí iná wọn ń jó wà níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje.


Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan