Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 1:8 - Yoruba Bible

8 “Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin, li Oluwa wi, ẹniti o mbẹ, ti o ti wà, ti o si mbọ̀wá, Olodumare.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 1:8
29 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé.


Ọlọrun Olodumare yóo bukun ọ, yóo fún ọ ní ọmọ pupọ, yóo sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.


Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde.


Kí Ọlọrun Olodumare jẹ́ kí ọkunrin náà ṣàánú yín, kí ó sì dá arakunrin yín kan yòókù ati Bẹnjamini pada. Bí mo bá tilẹ̀ wá ṣòfò àwọn ọmọ mi nígbà náà, n óo gbà pé mo ṣòfò wọn.”


Jakọbu sọ fún Josẹfu pé, “Ọlọrun Olodumare farahàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì súre fún mi.


Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá, yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.


Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ”


Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an.


Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni? Tí ó pe ìran dé ìran láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi OLUWA ni, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn.


OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn; kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì ye yín pé, Èmi ni. A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi, òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.


Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní, “Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin; lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.


“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu, ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè, Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀, èmi sì ni ẹni òpin.


Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.


ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀.


N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi, lọkunrin ati lobinrin yín. Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”


Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn.


Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀;


Wọ́n ní, “A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare, ẹni tí ó wà, tí ó ti wà, nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba.


wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé, “Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare. Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ, Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.


Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.


Mo bá gbọ́ tí pẹpẹ ìrúbọ wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, Ọlọrun, Olodumare, òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ.”


Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.


Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana: “Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:


N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀.


Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.”


Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé, “Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́! Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii, tí ó sì ń bọ̀ wá.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan