Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 1:5 - Yoruba Bible

5 ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé. Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 1:5
53 Iomraidhean Croise  

Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!


Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.


N óo fi ṣe àkọ́bí, àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.


Ẹlẹ́rìí òtítọ́ kì í parọ́, ṣugbọn irọ́ ṣá ni ti ẹlẹ́rìí èké.


Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan, olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.


Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.


A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.


Ṣugbọn ẹ̀wù tabi aṣọ, tabi ohun èlò awọ, tí àrùn yìí bá lọ kúrò lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́, kí olúwarẹ̀ tún un fọ̀ lẹẹkeji, yóo sì di mímọ́.”


OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.


Nítorí Ọmọ-Eniyan kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un; ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”


Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.


Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.


Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.


Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi.


Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”


Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, à ń sọ ohun tí a mọ̀, a sì ń jẹ́rìí ohun tí a rí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí wa.


Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.


Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀.


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.”


Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.


Ṣugbọn ninu gbogbo ìrírí wọnyi, a ti borí gbogbo ìṣòro nípa agbára ẹni tí ó fẹ́ràn wa.


Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.


Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi.


Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa,


Ẹ máa rìn ninu ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristi ti fẹ́ wa, tí ó fi ara òun tìkararẹ̀ rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí Ọlọrun nítorí tiwa.


Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.


Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín kò fetí sí ti Balaamu, ó yí èpè náà sí ìre fun yín nítorí pé ó fẹ́ràn yín.


Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti.


Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ.


Mo pá a láṣẹ fún ọ níwájú Ọlọrun tí ó fi ẹ̀mí sinu gbogbo ohun alààyè, ati níwájú Kristi Jesu tí òun náà jẹ́rìí rere níwájú Pọntiu Pilatu,


Ọlọrun yóo mú ìfihàn yìí wá ní àkókò tí ó bá wù ú, òun ni aláṣẹ kanṣoṣo, Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn oluwa;


Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́?


mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè.


Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n.


Ṣugbọn bí a bá ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, bí òun náà ti wà ninu ìmọ́lẹ̀, a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọmọ rẹ̀ sì ti wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa nù kúrò lára wa.


Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”


N óo fún àwọn ẹlẹ́rìí mi meji láṣẹ láti kéde iṣẹ́ mi fún ọtalelẹgbẹfa (1260) ọjọ́. Aṣọ ọ̀fọ̀ ni wọn yóo wọ̀ ní gbogbo àkókò náà.”


Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.”


Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun.


A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”


Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé: “Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní


Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan