Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 1:3 - Yoruba Bible

3 Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Olubukún li ẹniti nkà, ati awọn ti o ngbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ yi, ti o si npa nkan wọnni ti a kọ sinu rẹ̀ mọ́: nitori igba kù si dẹ̀dẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 1:3
15 Iomraidhean Croise  

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi, tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi, tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.


Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè.


“Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ).


Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”


Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ.


Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀.


Òpin ohun gbogbo súnmọ́ tòsí. Nítorí náà ẹ fi òye ati ìwà pẹ̀lẹ́ gbé ìgbé-ayé yín ninu adura.


Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan.


Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀.


“Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.


Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.”


Mò ń bọ̀ kíákíá. Di ohun tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má baà gba adé rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan