Ìfihàn 1:2 - Yoruba Bible2 Johanu sọ gbogbo nǹkan tí ó rí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀rí Jesu Kristi. Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Ẹniti o jẹri ọ̀rọ Ọlọrun, ati ẹrí Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí—èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.