Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 9:2 - Yoruba Bible

2 Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja Òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 9:2
16 Iomraidhean Croise  

Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.


Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.”


Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”


Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́.


Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.


Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.


Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo.


Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀, tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?


N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu.


Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu.


N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.


“N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.


Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan