Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 9:1 - Yoruba Bible

1 Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ỌLỌRUN si sure fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si kún aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 9:1
13 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.”


Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”


Ìdílé àwọn ọmọ Noa ni wọ́n jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìran wọn ní orílẹ̀-èdè wọn. Lára wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká gbogbo ayé lẹ́yìn ìkún omi.


Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀.


Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.”


Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde.


Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.”


Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé.


Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí.


“Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”


Ẹ yin OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA, tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀.


Ẹ wo Abrahamu baba yín, ati Sara tí ó bi yín. Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é, tí mo súre fún un, tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan