Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 8:1 - Yoruba Bible

1 Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ọlọ́run sì rántí Noa àti ohun alààyè gbogbo tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, bí àwọn ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn, ó sì mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì fà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 8:1
35 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.


Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀.


Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀,


Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.


Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀.


Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ.


mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so. Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.


Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé, bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀.


Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì, kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀, ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.


Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀, ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.


Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.


OLUWA ranti wa, yóo bukun wa, yóo bukun ilé Israẹli, yóo bukun ìdílé Aaroni.


OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.


Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;


OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá, tí wọn ń pariwo pé, “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”


OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi; OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.


Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.


Mose na ọwọ́ rẹ̀ sórí Òkun Pupa; OLUWA bá mú kí afẹ́fẹ́ líle kan fẹ́ wá láti ìhà ìlà oòrùn ní gbogbo òru náà, afẹ́fẹ́ náà bi omi òkun sẹ́yìn, ó sì mú kí ààrin òkun náà di ìyàngbẹ ilẹ̀, omi rẹ̀ sì pín sí ọ̀nà meji.


Ṣugbọn o fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, òkun sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rì bí òjé ninu ibú ńlá.


Ọlọrun gbọ́ ìkérora wọn, ó sì ranti majẹmu tí ó bá Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu dá.


Bí ẹ̀fúùfù ìhà àríwá tíí mú òjò wá, bẹ́ẹ̀ ni òfófó ṣíṣe máa ń fa kí a máa fi ojú burúkú woni.


Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ! n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’


Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn, kí àwọn odò wọn lè gbẹ! Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni, wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà.


OLUWA ti fi ògo Jakọbu búra; ó ní, “Dájúdájú n kò ní gbàgbé ẹyọ kan ninu iṣẹ́ ọwọ́ yín.


Ṣé kò yẹ kí èmi foríji Ninefe, ìlú ńlá nì, tí àwọn ọmọde inú rẹ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) lọ, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn tí ó wà ninu ìlú náà?”


Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ, ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu; koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ, òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀.


OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ, mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́; tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa; sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.


Wọn óo la òkun Ijipti kọjá, ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀, a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀, agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.


Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.


Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí.


Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀.


Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run, Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.


Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan