Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 7:9 - Yoruba Bible

9 ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 7:9
12 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́.


Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un.


Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.


Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji.


Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà.


Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀,


Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù, erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára. Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀; wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada. Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.


Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu.


Ninu ipò titun yìí, kò sí pé ẹnìkan ni Giriki, ẹnìkan ni Juu; tabi pé ẹnìkan kọlà, ẹnìkan kò kọlà, ẹnìkan aláìgbédè, ẹnìkan ẹlẹ́nu òdì, ẹnìkan ẹrú, ẹnìkan òmìnira. Nítorí Kristi ni ohun gbogbo, tí ó wà ninu ohun gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan