Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 7:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 7:1
26 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn.


Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA.


Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta;


Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi.


N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá.


Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.


Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà, níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.


Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára, olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.


bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.


Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.


Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé.


Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.”


Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo.


Àwọn wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nígbà kan rí, nígbà ayé Noa, nígbà tí Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ mú sùúrù tí Noa fi kan ọkọ̀ tán. Ninu ọkọ̀ yìí ni àwọn eniyan díẹ̀ wà, àwọn mẹjọ, tí a fi gbà wọ́n là ninu ìkún omi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan