Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 5:5 - Yoruba Bible

5 Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 5:5
21 Iomraidhean Croise  

Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.”


Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú.


Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi.


Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú.


Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé.


Adamu bí Seti, Seti bí Enọṣi.


Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú, ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.


Ta ló wà láyé tí kò ní kú? Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?


Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa; pẹlu ipá a lè tó ọgọrin; sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu; kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.


ẹ̀rù ibi gíga yóo máa bani, ìbẹ̀rù yóo sì wà ní ojú ọ̀nà; tí igi alimọndi yóo tanná, tí tata yóo rọra máa wọ́ ẹsẹ̀ lọ, tí ìfẹ́ ọkàn kò ní sí mọ́, nítorí pé ọkunrin ń lọ sí ilé rẹ̀ ayérayé, àwọn eniyan yóo sì máa ṣọ̀fọ̀ kiri láàrin ìgboro;


kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.


Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́.


Máa wọ aṣọ àríyá nígbà gbogbo, sì máa fi òróró pa irun rẹ dáradára.


Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.


Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”


Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan