Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 5:4 - Yoruba Bible

4 Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 5:4
17 Iomraidhean Croise  

Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”


Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela.


Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.


Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú.


Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.


Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.


“Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”


Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ; òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.


Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa, jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà, kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé, tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan