Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 5:2 - Yoruba Bible

2 Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 5:2
9 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.


Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”


OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀.


Ọkunrin náà bá wí pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi, ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi; obinrin ni yóo máa jẹ́, nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.”


Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.


Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.


Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn,


Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn.


Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan