Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 49:4 - Yoruba Bible

4 Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn, o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀, o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 49:4
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.


Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.


“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’ “Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’


Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní: “Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun, àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”


A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!


“ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya ẹlòmíràn, tabi ilé rẹ̀, tabi oko rẹ̀, tabi iranṣẹkunrin rẹ̀, tabi iranṣẹbinrin rẹ̀, tabi akọ mààlúù rẹ̀, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi ohunkohun tíí ṣe ti ẹlòmíràn.’


Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀,


Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.


Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan