Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 49:3 - Yoruba Bible

3 Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi, ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ, tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 49:3
17 Iomraidhean Croise  

Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.”


Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.


Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni.


Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀,


Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.”


Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni;


Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.


Àwọn ọmọ Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu, ni: Hanoku, Palu, Hesironi ati Kami.


Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.


O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu.


Ìpín ti Reubẹni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Efuraimu, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.


Ninu ẹ̀yà Reubẹni, tíí ṣe àkọ́bí Israẹli, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún ọdún sókè, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé


Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,


Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí.


Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra.


Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní: “Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun, àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé: “Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan